Yoruba

Ijoba Apapo Seleri Eto Ilera To Poju Owo

Ijoba apapo orileede yii, ti soodi mimo pe, oun yoo sise papo pelawon eka aladani lati fi mu amugbooro ba eto ilera to pojuowo nile Nigeria.

Alakoso keji, feto ilera nile yii, Senito Olorunnimbe Mamora, lo salaye eyi nilu Abuja nibi eto ipade kan tigbimo amuseya eyi t’ijoba Apapo gbekale foro Arun Covid-19 se pelu alaye pe, laifi ti akoba ti itankale Arun Corona ti se lorilede yii se, sibe ijoba yoo tesiwaju lati jeki eto abere ajesara ti too maa dena awon Arun lolokan o jokan jafasi.

Senito Mamora ki sai tun fowo idaniloju soya pe, ijoba yoo tubo kobiara soro eto abere ajesara bayii, paapa julo bi ile Nigeria se fe gba iwe Ase didena Arun ropa-rose lose yii. 

Folakemi Wojuade

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *