News Yoruba

Onímọ̀ ìsègùn sàtẹnúmọ́ ìdí fún ìtọ́jú ojú

Àwọn ọmọ olẹ̀ yí ni wọ́n ti gbà lámọ̀ràn láti máà sàyẹ̀wò ojú wọn ó kéré tán léèkan lọ́dún láti léè tètè kẹ́ẹ̀fín bí ojú bá ní ìpèníjà.

Olùtọ́jú ojú tíì tún se igbákejì ọ̀gá àgbà lẹ́ka olùtọ́jú aláisan nílé ìwòsàn ẹ̀kọ́sẹ́ ìsègùn U.C.H., arábìnrin Abiọla Agatha ló fàmọ̀nràn yi síta nígbàtí ó ńbá akọ̀ròyìn ilé isẹ́ prẹmier F.M sọ̀rọ̀ n;ilu ìbàdàn.

Arábìnrin Agatha ẹnití ó ní àwọn àrùn ojú tó sábà máà ńjẹyọ láti ara àwọn àisàn bí ìtọ̀ sugar, ẹ̀jẹ̀ ríru àti àijẹ óunjẹ téròjà rẹ̀ pé gba àwọn ènìyàn lámọ̀nràn kí wọ́n tètè lọ sílé ìwòsàn bí ojú wọn bá ńwami tó ńlẹ̀pọ̀ tàbí tó bá pọ́n tó sì ńdùn wọ́n.

Arábìnrin Agatha kò sài rọ wọ́n láti mú ìmọ́tótó ara àti àyíká lọ́kunkúdùn láti léè dènè àisàn ojú

Kẹhinde/Dada

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *