Yoruba

Kaadi Idanimo: Sisayewo Oye Awon Olugbe Igberiko Atesekuku

Oniruru igbese lo dabi pe ijoba ngbe bayi lati gbogun tiwa odaran lawujo, okan ninu re si nipe kawon eeyan ni kaadi idanimo torilede yi lowo.

Iwadi fihan pe latigba tijoba ti kede gbedeke asiko tawon eeyan gbodo se eleyi lawon budo tiwon ti nse eleyi ti beresi kun akunfaya.

Nje awon olugbe igberiko atesekuku tile mo idi tijoba fi pon ni dandan lati ni nomba idanimo torilede yi lowo bi?

Abewo sawon budo tiwon ti ngba kaadi idanimo lawon ijoba ibile bi afijio, atiba, iwo oorun atila oorun oyo fihan pe ise aselaagun lawon osise nse nibe.

 Idi abajo nipe suuru ogulogo awon eeyan tiwon nwa sawon budo oun ni ko to, tawon osise na si nkoju awon isoro bi airina oba lo.

Botilejepe awon osise lawon budo oun kogba pe ki a gba ohun awon sile, egbo die ninu iriri awon tofe gba kaadi idanimo nibe.

Nigba to nsoro, baale olori (r.m.d) oloye adekunle teslim kesi awon ilese elero ibanisoro lati wojutu sawon isoro tawon olugbe igberiko nkoju lori lilo foonu alagbeka.

Oga agba ajo eleto itaniji ta mo si national orientation agency, noa nijoba ibile ola oorun oyo, abileko florence siyanbade salaye bilana tijoba gbe kale se wulo to, tosi pe fun kawon eeyan tete gbe igbese.

Abileko siyanbade lawon si ntesiwaju nipa akitiyan lori bawon eeyan kose ni so anfani lilo foonu alagbeka won nitori igbese tijoba gbe yi.

Kayode Oguntona

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *