Yoruba

Ìjóba ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ní àjọsèpọ̀ pẹ̀lú Korea lórí gbígbé ètò ẹ̀kọ́ sórí ìkíni ayélujára

Gómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, onímọ̀ ẹ̀rọ Seyi Makinde ti sọpé ìsèjọba òun yo tẹ̀síwájú láti ma sàmúlò òpó ẹ̀rọ ayélujára láti mú kí ètò ẹ̀kọ́ bọ̀ sípò nípinlẹ̀ ọ̀yọ́.

Nínú àtẹ̀jáde èyí tí akọ̀wé àgbà sí Gómìnà lórí ọ̀rs ìròyìn, ọ̀gbẹ́ni Taiwo Adisa fisíta nílu’bàdàn, jẹ́ kó di mímọ̀ pé Gómìnà sọ̀rọ̀ yí lásìkò tón gba àwọn asojú láti ilẹ̀ Korea lálejò lọ́fìsì rẹ̀, ní secretariat.

Gómìnà tún sọ síwájú pé ìsèjọba òun ti setán láti sisẹ́ papọ̀ pẹ̀lú ilésẹ́ kan ní Korea tón mójútó ètò ẹ̀kọ́ tó pójúowó.

Àtẹ̀jájadé náà fikun pé àwọn ikọ̀yí lówà sí ìlú bàdàn láti sàbẹ̀wò isẹ́ àkànse pàtàkì lórí kíkọ́ iléwe ìgbàlódé èyí tí UBEC, ńse lọ́wọ́ lábúlé sógunró lópopónà Mọ́níyà ọ̀yọ́, níjọba ìbílẹ̀ Akinyẹle.

Nínú ọ̀rọ̀ ìkíni kábọ Gómìnà ló ti sàlàyé pé gẹ́gẹ́bí ara akitiyan ìsèjọba òun, láti mú kétò ẹ̀kọ́ kójúòsùwọ̀n, ìjọba ya owó ìdá mọ́kànlé lógún sí méjìlé lógún nínú ọgọ́run, sọtọ fún ẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́, nínú àbá ìsúná ọdún 2021.

Net/Afọnja

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *