Yoruba

Ile Igbimo Asofin Agba Seleri Lati Mu Agbega Ba Papako Ofurufu Ilu Ibadan Kolee Ba Igbamu

Ìgbìmò tekoto Ile asòfin Àgbà fétò Ìrìnnà ojú òfurufú ti sèlérí pé, òun yóò mú àgbéga bá pápákò òfurufú ilè yìí to wà nílu ìbàdàn, lónà tí yóò fi ba ìgbàmu.

Alága ìgbìmò tekoto Ile asòfin Àgbà fétò Ìrìnnà ojú òfurufú náà, sénítò Smart Adéyemí, ló sàlàyé èyí làkókò àbèwò won sí Gómìnà Sèyí Mákindé lóluulésé ìjoba tówà ladugbo Agodi nilû ìbàdàn gégé bí ara akitiyan ìgbìmò náà.

Sénítò Adéyemí sàlàyé pe, àbèwò won òhún sáájú àgbékalè àbá òfin odún 2022 ni yóò ró ìgbìmò tekoto Ile náà lagbara pelawon ìroyìn to wúlóò, èyí tó n dé sétìgbó rè, láti le rí owó goboi ná séka ètò Ìrìnnà ojú òfurufú.

Nínú òrò tálága ìgbìmò tekoto Ile asòfin kejì fétò Ìrìnnà ojú òfurufú, ògbéni Nnolim Nnaji, to n náà kówòrìn pelu ikò òhún tenumó pàtàkì mímú àgbéga báwon pápákò òfurufú to n be nílè yìí, gégé bí ojú ònà mín táwon eeyan n samulo fétò Ìrìnnà, niwoyesi okanojokan awon ipenija to nkoju ètò àbò.

Nínú òrò tie, Gómìnà ipinle oyo, Onímòèro Sèyí Mákindé to ìjoba àpapo pe , kó jòwó pápákò òfurufú náà fun ìjoba ipinle Oyo, lónà àti fun lanfani atunse re ni kiakia, nibamu pelu ajosepo to dammoran laarin re ati ìjoba àpapo.

Leyin eyi ni ikò òhún wa se àbèwò lo si pápákò òfurufú ilu ìbàdàn, láti le mo ipo to wa gan.

Folakemi Wojuade.

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *