Níbàyíná, asojú pàtàkìlájọ ìsọ̀kan àgbáyé arábìnrin Leilana Fartha, ti rọ ìjọba àpapọ̀ láti máà gbé gẹ́gẹ́ owó orí sísan láwọn ilégbe ìjọba tíkò sáwọn èèyàn níbẹ̀ lọ́nà àti fi wójùtú sọ́kanòjòkan ìsòro àinílélórí tó ńkojú àwọn èèyàn ilẹ̀ Nàijírìa.

Arábìnrin Fartha ló fìdí èyí múlẹ̀ nílu Abuja, tó sì fàidunú rẹ̀ hàn lórí àwọn ìpèníjà tónkojú ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, èyí tàisi ìgbàyé tó fararọ ń sokùnfà rẹ̀.

Nígbà tó ń gba ìjọba àpapọ̀ níyànjú láti tètè gbé ìgbésẹ̀ akin fi wójùtú sí ìsòro àirílégbé àti isẹ́, arábìnrin Fartha, wá bèèrè fún dídáwọ́kọ́ lórí míma fi tìpá tìkúuku lé àwọn èèyàn jáde.

Kò sài tún rọ ìjọba láti wójùtú sọ́rọ̀ àitọ́ ilégbe tó gogo, pẹ̀lú wíwá ọ̀nà àbáyọ sáwọn ìpèníjà tó ń kojú ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn.

Dada/Alamu

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *