Ilé isẹ́ ọmọ ológun orílẹ̀dè yíì, ti ké sáwọn aráalu láti máà se fòyà rárá lórí ìgbésẹ̀ ìbọn yínyìn tí yóò wáyé lákokò ayẹyẹ àyájọ́ òmìnira ilẹ̀ fún tọdún 2019 tawàyí.
Èyí ló jẹyọ nínú àtẹ̀jáde kan tígbákejì olùdarí agbẹnusọ fún ilé-isẹ́ ológun náà, ọ̀gágun Haruna Tagwai fisíta nílu Abuja.
Ọgagun náà tó tọ́kasi pé, ayẹyẹ òmìnira ilẹ̀ yíì tójẹ́ ọdún kọkàndínlọ́gọ́ta ni yóò wáyé lọ́jọ́ ìsẹ́gun nílé àarẹ tó wà nílu Abuja, wá rọ àwọn ọmọ orílẹ̀dè yíì láti máà se fàayè gba ìbẹ̀rù kankan lọ́ọ́kan àyà wọn lọ́jọ́ náà.
Agbẹnusọ fúnlesẹ́ ológun ọ̀hún kò sài sọ́ọ́di mímọ̀ pe, ìgbésẹ̀ ìbọn yínyìn náà ló wà lára akitiyan tó ń sàmì ayẹyẹ ọjọ́ òmìnira ọ̀hún.
Kẹmi Ogunkọla/Osamudiamen Idemudia