Lẹ́yìn osù mẹ́tàléláadọta tí wọ́n sàgbéga fún àwọn ọba kan nílu ìbàdàn látọ̀dọ̀ Gómìnà àná nípinlẹ̀ Ọyọ Sẹnatọ Abiọla Ajimọbi, ilé ẹjọ́ gíga ti ìpínlẹ̀ yí ti wọ́gilé ilé ìwé òfin tí wọ́n tẹ̀lé láti sàgbéga ọ̀hún.

Nígbàtí ńfọwọ́sí àdéhùn yíyanjú ẹjọ́ tí ìjọba ìpínlẹ̀ yi àti èyí tí òsì Olúbàdàn Olóyè Rashidi Ladọja jọ jùmọ̀ pè, onídajọ́ Aderẹmi sọpé, nígbàtí gbogbo àwọn tọ́rọ̀ kan tidìjọ fẹnukò, kò sí ǹkan kan miràn mọ̀ jupe kóun wọ́gilé òfin àtúntò ọ̀rọ̀ oyè ọ̀hún lọ.

Olóyè Ladọja lọ́dún 2018 ló jáwé olúborí níbi ìgbẹ́jọ́ tó gbígilé ìlànà díde àwọn olóyè ẹgbẹ́ rẹ̀ àti àwọn baalẹ kan ládé tí wọ́n tó mọ́kànlélógún níye lósù kẹjọ ọdún 2017 tí ìjọba Sẹnatọ Ajimọbi se.

Gómìnà Seyi Makinde ló yan láti yanjú àawọ ọ̀hún tó ti sọ àwọn ọba makànlélógún ọ̀hún di olodi olúbàdàn ti ilẹ̀ ìbàdàn, ọba Saliu Adetunji di ọ̀tá láti ọdún 2017 nítùbí ìnùbì. Dada Yẹmisi

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *