Yoruba

Ijoba Apapo Jeje Ifesemule Oro Aje Sii

Awon eto to wa fun ifesemule oro aje ti ijoba apapo ti won fi sori mimu adinku ba ipa ti arun covid-19 lori oro aje ile yi ni won yio bere si samulo re laarin osu mejila to nbo.

Oluranlowo Pataki si Aare lori oro ara ilu, ogbeni Ajuri Ngelale lo soro yi nigbati o nkopa lori eto kan lede geesi lori ile ise Radio Nigeria apapo ti a mo si “Politics Nationwide”.

Ogbeni Ngelale ni awon omo orile ede yi ko ni pe beere si ri ipa ti awon ilana to wa fun ifesemule oro aje leyi ti won fi lee Aare Buhari lowo lenu kopekope yi lati owo awon igbimo ti igbakeji Aare Ojogbon Yemi Osinbajo lewaju re.

Ogbeni Ngelale ni ijoba apapo ti nsise ni ifowosowopo pelu ile igbimo Asofin Apapo ati awon gomina lati lee wa owo ti won nilo lati fi muki awon ilana naa wasi imuse.

Awon to pe sori eto naa wa ro Ijoba apapo lati keko ninu oro ajakale arun covid-19 yi ki won bere si nii ronu lori ona ti won fi lee dari oro aje gba ona miran bii si eto ogbin ati imo ero.

Oluyemisi Dada

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *