Yoruba

Àjọ INEC sún ètò àtúndì ìbò yíká orílẹ̀èdè yíì síwájú

  Àjọ elétò ìdìbò nílẹ̀ yíì, INEC, ti sún ètò àtúndì ìdìbò tóyẹ kówáyé lọ́jọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n osù yíì, láwọn ìpínlẹ̀ mọ́kànlá nílẹ̀ yíì síwájú.

 Alákoso àti alága fọ́rọ̀ ìròyìn àti ìgbìmọ̀ ìlanilọ́ọ̀yẹ̀ àwọn olùdìbò, ọ̀gbẹ́ni Festus Okoye, ẹnitó tó sọ̀rọ̀ yíì nílu Abuja, sọpé àjọ náà gbé ìgbésẹ̀ lẹ́yìn ìpàdé pàjáwìrì láti sàtúngbéyẹ̀wò ètò àbò láwọn apá ibìkan ill yíì.

Ọgbẹni Okoye sèlérí pé àjọ náà yóò tẹ̀síwájú láti máà tọọpinpin bí ǹkan se ńlọ láwọn ìpínlẹ̀ àtàwọn ẹkùn ìdìbò, tí yóò sì késí àwọn tọ́rọ́ọ̀kàn lọ́sẹ̀ méjì sí àsìkò yíì láti sàtún-gbéyẹ̀wò ọ̀rọ̀ náà.

Àmọ́ sáà, ó rawọ́ ẹ̀bẹ̀ fáwọn tọ́rọ̀ kàn àtàwọn olùdìbò láwọn ìpínlẹ̀ tóòyẹ kétò ìdìbò náà tí wáyé láti dákun-dáàbọ̀ níì súùrù.

 Jeff/Idogbe  

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *