Ilé- ẹ̀kọ́ gíga fasity Leadcity ìbàdàn ti sàlàyé pé, àwọn ọ̀dọ́ tó wá látapá àríwá ilẹ̀ yíì, pẹ̀lú ọkọ̀ akérò bus ńlá kan wá ságbègbè sókà lọ́jọ́ ajé, akẹ́kọ́ọ̀ ilé-ìwé náà niwọ́n se.

Sáajú níbẹ̀rẹ̀ ọ̀sẹ̀ yíì nìròyìn náà gbòde kan pé, bí ọ̀ọ̀dúnrún àwọn tíwọ́n furasí bí darandaran ti yawọ agbègbè Sókà, lórí èróngbà tíwọn kò sọ́ọ̀di mímọ̀.

Ìgbésẹ̀ náà wá ń dá ìpayà sílẹ̀ lókàn àyà àwọn olùgbé ibẹ̀.

Àmọ́ níbàyí agbẹnusọ ilé-ẹ̀kọ́ náà tón tún rísọ́rọ̀ àwọn akẹ́kọ́ọ̀, ọ̀mọ̀wé Ayọbami Owolabi sọ́ọ̀di míms pé, márùndínlógójì péré, láwọn ọ̀dọ́ náà tó jànfàní ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ lábẹ́ ètò WAMAKO Foundation.

Kò sài tún tọ́kasi pé, àti ìpínlẹ̀ Sokoto làwọn akẹ́kọ́ọ̀ náà tiwá láti dé sí ibùdó tíwọ́n ti se lọ́jọ̀ fún wọn ládugbò sókà, àmọ̀, tóní dídé wọn se àjèjì fàwọn olùgbé agbègbè Sókà, èyí tómú wọn ké gbàjerè.

Olórí agbègbè Sókà níbẹ̀, Olóyè Ọladokun, sọ pé, ìgbésẹ̀ wọn mú ìfura lọ́wọ́, tó sì dá ìpayà sílẹ̀, pẹ̀lú àtọ́kasí pé ilé-isẹ́ ọlọ́pa tó wà ládigbò Sányò làwọn kówọn lọ, kó tó dipé ilé-ẹ̀kọ́ gíga fasity Leadcity fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé akẹ́kọ́ọ̀ ilé-ẹ̀kọ́ náà niwọ́n se.

Nígbà tó ńfìdí ìgbésẹ̀ náà múlẹ̀, agbẹnusọ ilé-isẹ́ ọlọ́pa ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, ọ̀gbẹ́ni Olugbenga Fadeyi sọpé àwọn ọ̀dọ́ náà wá sílu ìbàdàn láti wá parí ètò ẹ̀kọ́ wọn ni, nílé ẹ̀kọ́ gíga fasity Leadcity, ìbàdàn, èyí tí Gómìnà tẹ́lẹ̀ nípinlẹ̀ Sokoto sonígbọ̀wọ́ wọn.

Dayọ/Ibomor/Wojuade

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *