Ìjọba àpapọ̀ ti pàsẹ fáwọn àjọ aláàbo tó wà láwọn ẹnu ìloro àwọn ilé-isẹ́ ìjọba látiridájú pé, àwọn òsìsẹ́ ìjọba tó wà lákàsọ̀ kẹtàlá sókè niwọn gba láàye láti wọ àyíká àwọn ilé-isẹ́ ọ̀hún.


Èyí ló wáyé nípasẹ̀ àsẹ tígbìmọ̀ amúsẹ́yá ilé isẹ́ àarẹ lórí covid 19, pé káwọn òsìsẹ́ tó wà lákàsọ̀ kejìlá sísàlẹ̀ gbélé wọn fún gbèdéke ọ̀sẹ̀ márun, gẹ́gẹ́ bí ara ìgbésẹ̀ láti dènà ìtànkálẹ̀ kòkòrò àrùn ọ̀hún.


Olórí òsìsẹ́ nílẹ̀ yíì, Arábìnrin Fọlasade Yẹmi Ẹsan ló pàsẹ náà fáwọn àjọ aláàbo min àtẹ̀jáde kan tíwọ́n fisita nílu Abuja.


Kò sài fikun pé, àwọn òsìsẹ́ tọ́rọ̀kàn nìrètí wàpé, wọ́n yóò máà sisẹ́ wọn látilé.


Aminat Ajibikẹ/Fọlakẹmi Wojuade

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *