Yoruba

Bánki àpapọ̀ ilẹ̀ yíì, CBN, sàgbékalẹ̀ ìlànà ẹ̀rọ atètè dánhun sọ̀rọ̀ owó sísan

Ilé ìfowópamọ́ àpapọ̀ ilẹ̀ yíì CBN, ti sí sísọ lójú ìlànà ẹ̀rọ ìsanwó kan èyí tíwọ́n yóò tètè máà dánhun sáwọn ọ̀rọ̀ tóníse pẹ̀lú owó sísan léyi tí yóò lọ́wọ́ àwọn tón gbéjáde àtàwọn olùkópa min-in lórílẹ̀dè yíì látiridájú pé wọ́n ń sàmúlò ìlànà ọ̀hún.

Ilé ìfowópamọ́ àpapọ̀ náà sọ́ọ̀di mímọ̀ pé, àwọn ìlànà ọ̀hún ló wà látiridájú àbò àti ìdúrósinsin wà lẹ́ka ìlànà ìsanwó látorí ẹ̀rọ ayélujára.

Gẹ́gẹ́ bí ilé ìfowópamọ́ náà sewipe, wọ́n le lọ ìlànà ọ̀hún láti fi se àkọsílẹ̀ àti fífi ẹri owó sísan sọwọ.

Bánki àpapọ̀ náà wá sèkìlọ̀ pé, ìjìyà tó dógbun wà ńlẹ̀ fẹ́ni yóòwo tó bá kùnà láti tẹ̀lé àwọn ìlànà ọ̀hún lọ́nà tótọ́, pẹ̀lú àfikún pé gbogbo àròyé àwọn oníbara pẹ̀lú ìlànà àbò tile ìfowópamọ́ àpapọ̀ ilẹ̀ yíì gbékalẹ̀.

Net/Wojaude

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *