Yoruba

Àwọn Tọ́rọkàn Pe Fùn Sísamúlò Òfin Lọna Ati Mópinba Awọ́ọ̀ Lárin Àwọn Àgbẹ̀ Àtàwọn Darandaran

Ìpàdé èyítí àwọn onímọ̀ nípa ǹkan ọ̀gbìn, àwọn lọ́ga lọ́ga lẹ́nu isẹ́ ọba, àtàwọn àgbẹ̀, lágbègbè Ìbàràpá nípinlẹ̀ ọ̀yọ́, niwọn ti pèfún, sísàmulò àwọn òfin tó wà ńlẹ̀ èyí tóníse pẹ̀lú kíkó ẹranjẹ̀ lójú-táàyé àti fífòpinsi káwọn bòròró daran-daran má mú ohun ìjà olóró kiri.

Ìpàdé ọ̀hún èyí tónrísí ìdájọ́ òdodo ìdàgbàsókè àti àláfìa gbékalẹ̀ èyí tó fojúsùn wíwa ojútu sí awọ́ọ̀ lárin àwọn àgbẹ̀ àtàwọn daran-daran tó wáyé lẹ́nu lọ́lọ́yi nípinlẹ̀ ọ̀yọ́ àti fífòpinsí ètò ìrìnáà lọ́nà àitọ́.

Àwọn àgbẹ̀ tó fi ẹ̀rí ma jẹ́ mi ǹsó, ìkọlù wọn àti okoo wọn, koròju síì ìdíwọ́ tó ńwáyé lórí sísàmúlò òfin tóòde kíkó ẹranjẹ̀ lójútáyé nípinlẹ̀ ọ̀yọ́.

Méjì nínú wọn wá bèrè fún àbò tógbópọn lórí oko wọn, àti ìforúkọsílẹ̀ àwọn daran-daran níjọba ìbílẹ̀ láti dáà àláfìa padà sarin àwọn àgbẹ̀ àtàwọn daran-daran.

Asòfin tón sojú ẹkùn àríwá àti àringbùngbùn Ìbàràpá títún se alága ìgbìmọ̀ tẹkótó ilẹ̀ fọ́rọ̀ ọ̀gbìn, ọ̀gbẹ́ni Peter Ọjẹdokun sọpé, ìjọba kòní káàrẹ nídi dídásí ọ̀rọ̀ àwọn àgbẹ̀ àtàwọn daran-daran láti fẹsẹ̀ àláfìa múlẹ̀ sinsin.

Sáàjú, olùdarí àjọ tónrísí ìdájọ́ òdoodo, ìdàgbàsókè àti àláfìa nílu ìbàdàn, ẹniọ̀wọ̀ Ade Owoẹyẹ rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àwọn ilésẹ́ ìròyìn láti máà jábọ̀ awọ́ọ̀ pllú ikosemose lai léja nbákàn nínú.

Mosope Kehinde/Elizabeth Idogbe

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *