Yoruba

Awon Onimo Nipa Eto Ilera Tenumo Imototo, Lati Dena Arun Onigbameji

Awon onimo nipa eto ilera ti gbawon olugbe ipinle Oyo niynaju lati maa sora se kiwon si mu awon ilana atale eyi toun fun didena itankale kokoro arun COVID-19 lokunkundun.

Lakoko ti won b’oniroyin soro lori ibesile arun onigbameji to waye lenu loolo yii, niwon gbawon niyanju naa, okan lara won, Dokita Zainab Agboola se’kilo fawon eeyan lati yago kuro nidi mimu awon oun ti ko mo, atawon ounje ti ko kun fun ilera to jipepe.

O ni sise eto imototo ara eni ati taayika, owo fifo lorekoore, kawon ounje jije naa wa ni gbigbona ko si maa je dide ti ko ba ti setan fun jije lati dena aisan onigbameji.

Nigba ton naa soro olutoju alaisan kan, Arabinrin Temitayo Olatunji menuba awon ona teeyan le gba lati pinwo arun Cholera.

Arabinrin Olatunji wa gbawon omo orileede yii nimoran lati tubo tepele mo pipa awon ofin at’ilana to ro mo didena itankale arun COVID-19 mo, nitori pe, o si ja rainrain kiri yika agbaye.

Folakemi Wojuade/Seyifunmi Olarinde

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *