Yoruba

Ìjànbá ọkọ̀ gbẹ̀mí eeyan mẹ́tàlá lópopónà márọsẹ́ Èkó sí Ìbàdàn

Àwọn mẹ́tàlá ni wọ́n gbẹ́mi min tí àwọn méjìlá min sí farapa nínú ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé lópopónà másọsẹ̀ ìbàdàn sí Èkó.

Gẹ́gẹ́bí ohuntí ìròyìn wí, ìsẹ̀lẹ̀ náà ló wáyé láàrin ọkọ̀ èrò tó ńrìnrìn àjò bọ̀ láti ìlú Èkó àti ọkọ̀ akẹ́rù tó wáyé lójú kan níwájú ilé isẹ́ tó ńse ohunti wọ́n fi ńbolé àti àwọn ọ̀pá omi.

Àwọn òsìsẹ́ àjọ tó ńdarí ọkọ̀ sọ wípé awakọ̀ ọkọ̀ èrò náà ló ya ọkọ̀ sílẹ̀ lọ́nà tí kò tọ́ tó sì ló rọ́lu ọkọ̀ akẹ́rù tó kó ilẹ̀ níbi tí ó bájẹ sí.

Àwọn òsìsẹ́ àjọ tó ńdarí ọkọ̀ náà ni àwọn mẹ́san ló kú lójú ẹsẹ̀ nígbàtí àwọn mẹ́rin min kú nílé ìwòsàn níbití wọ́n ti ńgba ìtọ́jú.

Ìròyìn fikun wípé àwọn méjìlá tí wọ́n farapa ni wọ́n si ti gbé àwọn tókú sí ilé ìgbóku pamọ́sí tó wà nílé ìwòsàn kan náà.

Femi Dadamola

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *