Ìjọba àpapọ̀ ti ń gba lérò láti máà san ẹgbẹ̀rún márùndínlọ́gọ́rin fún ìdajì sa ètò ẹ̀kọ́ fáwọn akẹ́kọ tó n kọ ẹ̀kọ́ ìmọ̀ olùkọ́ lọ́wọn ilé ẹ̀kọ́ ìjọba àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà àdọ́ta fáwọn tó bá ń kẹ́kọ nílé ẹ̀kọ́sẹ́ olùkọ́ nílẹ̀ yí.

Alákoso fétò ẹ̀kọ́, Ọ̀gbẹ́ni Adamu Adamu ló sọ̀rọ̀ náà lásìkò ayẹyẹ àyájọ́ ọjọ́ àwọn olùkọ́ tó wáyé nílu Abuja, pẹ̀lú bẹ, ìjọba àpapọ̀ tún ti bẹ̀rẹ̀ ètò owó ìrànwọ́ fáwọn akẹ́kọ tamọ̀ sí Bursary.

Ilé isẹ́ ètò ẹ̀kọ́ tún sọpé oun yóò sisẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àjọ tón rísí ètò ẹ̀kọ́ láwọn ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì tó fi mọ́ olú ìlú ilẹ̀ yí láti mọ irúfẹ́ ẹ̀ka ẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́ tí yóò jànfàní náà, léyi náà ti àpapọ̀ ẹgbẹ̀rún lọ́nà àdọ́ta yóò máà di sísan fáwọn akẹ́kọ àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́run fáwọn akẹ́kọ ilé ẹ̀kọ́ ẹ̀kọ́sẹ́ olùkọ́, NCE, nílẹ̀ yí.

Ọgbẹni Adamu yan pé àwọn tí yóò jànfàní ló gbọdọ lọ sílé ẹ̀kọ́ ìjọba, tí wọ́n gbọdọ fọwọ́ síwe láti sojú ìpínlẹ̀ wọn fún ọdún márun.

Gẹ́gẹ́ bóse wí, owó na eto ohun ni jọba yóò ri láti àjọ elétò ẹ̀kọ́ káríayé, UBEC, àjọ tón mójútó ètò ẹ̀kọ́ gíga.

Pẹ̀lú àmójútó àjọ ìjọba àpapọ̀ tón rísí ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́.

Ọmọlọla Alamu/Ayọdele Ọlaọpa

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *