Gbogbo ǹkan ló ti padà bọ̀ sípò báyi nílé ìwòsàn ẹ̀kọ́sẹ́ ìsègùn òyìnbó ìlú ìbàdàn ìyẹn UCH, lẹ́yìn osù diẹ tí ẹgbẹ́ àwọn dókítà tó n fìmọ̀ kún ìmọ̀ láwọn ilé ìwòsàn ìjọba àpapọ̀ ti dasẹ́ sílẹ̀.

Gẹ́gẹ́bí akọ̀ròyìn ilé isẹ́ Radio Nigeria sewí, àwọn dókítà tọ́rọkàn ni wọ́n se isẹ́ wọn bóse tọ́ lóni.

Àarẹ ẹgbẹ́ náà nílè ìwòsàn UCH, ìbàdàn, Dókítà Temitọpẹ Hussein tó wà níkàlẹ̀ láti ri dájú pé gbogbo ǹkan lọ bóse tọ́ sàlàyé pé ìdákan àti àbọ̀ ìbere wọn ló ti di mímúsẹ báyi.

Dókítà Hussein sàlàyé pé ẹgbẹ́ NARD, ló bèrè fún àgbéyẹ̀wò owó ìrànwọ́ ewu ẹnu isẹ́ àti sísan owó ìrànwọ́ èwu tó rọ̀mọ́ ti covid tó fi mọ́ sísan àjẹsílẹ̀ owó osù àwọn.

Ẹwẹ, ẹnìkan tójẹ́ mọ̀lẹ́bí ẹnìkan tón gbàtọ́jú lọ́wọ́ tí kò fẹ kí wọ́n dárúkọ òhun, sọpé òun si nígbàgbọ́ tó kún nínú ilé ìwòsàn ìjọba ju ti aládani lọ.

Ilé isẹ́ Radio Nigeria jábọ̀ pé ìwọ̀nba aláisan péréte lówá nínú ilé ìwòsàn náà.

Tába gbàgbé pé ọjọ́ àikú Sunday ni ẹgbẹ́ àwọn dókítà tón fìmọ̀ kúmọ̀ láwọn ilé ìwòsàn ìjọba àpapọ̀ sélérí àti padà sẹ́nu isẹ́ léyi ìpàdé tí wọ́n se pẹ̀lú ìjọba àpapọ̀.

Lilian Ibomor/Ayọdele Ọlaọpa

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *