Ilésẹ́ tón rísí ìrìnà ojú irin ti fòfinde ìrìnà láti Abuja lọ sí Kaduna, tí kò sì ní gbèdéke.

Ilésẹ́ náà ló jẹ́ kọ́rọ̀ yí di mímọ̀ nínú ọ̀rọ̀ tó fi síta lójú òpó abẹ́yẹ fò twitter rẹ̀ lóòrọ yi.

Ó sọ pé ìfòfindè náà ló wáyé fún àwọn ìdí tí wọ́n kò lérò, tó sìní wọ́n yo sọ̀rọ̀ lórí rẹ̀ láipẹ.

Ilésẹ́ náà tún sọpé àwọn agbésùnmọ̀mí kan tún ju àdó olóró sí ojúrin Abuja lọ sí Kaduna, tí wọ̀n sì kojú ọkọ̀ ojúrin tó ní ọ̀pọ̀ èrò nínú lálẹ́ ọjọ́ ajé.

Bákanà ni wọ́n filéde pé àwọn ilésẹ́ alábo ti lọ sí ibi ìsẹ̀lẹ̀ náà.

Ikọ̀lú ọ̀hún ló wáyé, lẹ́yìn ọjọ́ diẹ, táwọn agbésùmọ̀mí kọlu pápákọ̀ òfurufú Kaduna, níbití wọ́n kò ti fàyè gba kí ọkọ̀ báàlù kó fóò.

Ololade Afọnja 

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *