Ètò ìwóde Egbé àwon òsìsé NLC ti wáyé yíká àwon ìpínlè lorilede yí.

 Ètò ìwóde náà tegbe àwon òsìsé gùnlé lo wáyé láti fi sàtìleyìn fun ìyansélódì Egbé ASUU to nlo lówó, tíwón si tún fi n sàfihàn àìdùnú lori owó tíjoba àpapò mórò ìyansélódì olósè méjìlá Egbé ASUU náà.

Àbò ìròyìn láti àwon ìpínlè bíi Èkó, Ògùn, Òndó, Òyó, Edo, Benue atawon ìpínlè mín-ìn torokan, sàfihàn bétò Ìwóde Egbé NLC se n lo, eyi tíwón ti gùnlé bayii káàkiri agbègbè.

Īko àwon oníròyìn wa, tó topinpin náà selo jábò pé, wámúwámú lawon àjo alaabo duro síbi tàwon ìwóde náà ti n wáyé, kawon jàñdùkú ma ba soòdi nnkan min-in mo won lówó.

Alága egbé àwon òsìsé lawon Ile Èkó gíga fásitì, ASUU tilé Èkó gíga fásitì ìbàdàn, Òjògbón Ayoola Akinwole, salaye pé, ètò ìwóde náà tàwon gùnlé, lawon fi n fi àìdùnú àwon hàn lori Ònà ti ijoba àpapò n gbà mórò ìyansélódì olósè méjìlá Egbé Asuu to nlo lówó ati lati Fi bèèrè, fún gbogbo ètò àwon.

 Nígbà tó n náà n sòrò, Alága Egbé Asuu tilé Èkó gíga fásitì ìmò-èro ládòkè Akíntólá nílùú Ògbómòsó, Òjògbón Biodun Olaniran, naa sàlàyé pé, ìyansélódì Òhún yóò mú àtúntò tó gbogbón bá ètò Èkó lawon Ile Èkó gíga fásitì ilè Nigeria, ti yóò sì tún dábò ò bo ojó òla àwon òdó.

Ní ti agbègbè Ìkejà nípìnlè Èkó ni ogunlógò àwon olùfèhónúhàn tígbà ìgboro kan pèlú òkanojokan àkolé lówó, nínú èyí tatiri, “e yé gbépo wolé látilè òkèrè mo” E sàtúse àwon ībùdó ìfopo wa, orilede Nigeria pe Ogota odún , Ebi si tún n pa araalu, e bawa wankan sesi.” 

Òrò ko yàtò nílùú Àkúré tii oluulu ìpínlè Òndó, Nibi teto ìwóde Egbé NLC ti nlo lówó ,tàwon olùfèhónúhàn náà si gbe àwon àkolé bíi, “O ti to get, e fopin si ìyansélódì Egbé Asuu to nlo lówó, kawon Omo wa le pada sile Èkó.

Net/ wojuade.

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *