Àarẹ Muhammadu Buhari ti gba ẹ̀bẹ̀ àarẹ orílẹ̀èdè South-Africa, Cyril Ramaphosa sí ilẹ̀ yíì, lórí ìkọlù tówáyé lórílẹ̀dè náà.

Àarẹ Buhari ẹnitó sàpèjúwe ìkọlù náà gẹ́gẹ́ bí èyító burú jai, fọwọ́ ìdánilójú sọ̀yà pé, ìbásepọ̀ tódánmọ́rán yóò wáyé lọ́tun l’árin àwọn orílẹ̀èdè méjèjì.

Ó mu wá sí ìrántí pé, ilẹ̀ Nàijírìa kó ipa takun-takun fún ilẹ̀ South-Africa nínú ìjìjàgbara kúrò lọ́wọ́ ìjọba ẹlẹ́yà mẹ̀yà èyí tí kò hàn sọ́pọ̀ ọ̀dọ́ ilẹ̀ South-Africa.

Àarẹ Buhari gba ìwé ẹ̀bẹ̀ ẹ̀foríjìyà Àarẹ Ramaphosa látọwọ́ alábasisẹ́pọ̀ pàtàkì rẹ̀, ọ̀mọ̀wé K. Mbatta àti Jeff Radebe, nílé àarẹ nílu Abuja.

Kemi Ogunkọla/Lara Ayọade

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *