Yoruba

APC ati PDP fesi si idajo ile ejo kotemilorun gbekale lori idibo Gomina ipinle Oyo

Awon alatileyin egbe oselu Peoples Democratic party, PDP, ati All Progressives Congress, APC, lo n sope oludije awon lo jawe olubori nibi eto idajo t’ile ejo kotemilorun to fikale s’ilu Ibadan gbe kale lori awuyewuye tosuyo nidi eto idibo sipo Gomina n’ipinle Oyo.

Oludije sipo gomina labe asia egbe oselu APC, Oloye Adebayo Adelabu nibi eto idibo to waye l’ojo kesan, osu kefa, lo pe ejo kotemilorun leyin ti ile ejo to ngbo awuye-wuye eto idibo daa ejo won nu, to si fidi ijawe-olubori Gomina Seyi Makinde mule.

Ile-ejo kotemilorun sope, ijawe olubori Gomina Seyi Makinde eyi ti igbimo to ngbo awuye-wuye esi idibo gbe kale kun oju osuwon too, pelu alaye pe, oye katungbeyewo ejo naa waye amo ti gbedeke ogosan ojo tofin la kale fun igbimo naa ti koja.

O wa sope ki nkan wa bose wa, saaju idajo igbimo ton gbo awuye-wuye esi idibo leyi to nfidi Onimoero Seyi Makinde, mule gege bi Gomina.

Nibamu pelu idajo naa, awon ololufe egbe oselu APC lawon agbegbe kan nilu Ibadan, nsajoyo lori idajo naa, tawon ololufe egbe oselu PDP miin naa sit un ndunnu pea won lawon jawe olubori ninu eto idajo ohun.

Nigba to nfesi Gomina Seyi Makinde sope mimi kan omi ohun gege bi Gomina toripe, kosi idajo kankan to tako iyansipo oun.

Ewe, atejade eyiti oluranlowosakowe ibaralusoro f’egbe oselu APC n’ipinle Oyo, Omooba Ayobami Adejumo fisita sope egbe oselu naa yoo pejo losi ile-ejo togajulo lati le fidi ijawe olubori won mule.

Oluwayemisi Dada/Kemi Ogunkola

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *