September 23, 2020
News Yoruba

Ilésẹ́ ọlọ́pa nípinlẹ̀ Ògùn nawọ́ gán àwọn tíwọ́n furasí pé wọ́n gbẹ̀mí òsìsẹ́ ọlọ́pa kan.

Ọwọ́ sìkún ilésẹ́ ọlọ́pa nípinlẹ̀ Ògùn ti tẹ àwọn mẹ́rin tíwọ́n furasí wípé wọ́n lọ́wọ́ nínú bíwọ́n senáà òsìsẹ́ ọlọ́pa, ọ̀gbẹ́ni Agada Akoh tí wọ́n sì gbẹ̀mí rẹ̀ lágbègbè dálémọ Sángo Ọtta nípinlẹ̀ Ògùn.

Nínú àtẹjade kan tí agbẹnusọ ilásẹ ọlọpa nípinlẹ Ògùn, ọgbẹni Abimbọla Oyeyẹmi fisíta sàfinhàn orúkọ àwọn tíwọn furasí ohun, Jẹlili Ismaila, Amidu Bankọle, Elijah Samson àti Moses Proboye.

Ó sàlàyé pé àwọn tíwọn furasí ọhun lọwọ tẹ nibiti ìsẹlẹ náà ti wáyé lásìkò tí òsìsẹ ilésẹ ọlọpa náà síwa nínú agbára ẹjẹ.

Ó sàlàyé pé, ọlọpa ohun ní wọn gbé dìgbà-dìgbà lọsí ilé ìwòsàn àmọ tó gbẹmimi lákokò tó ńgba ìtọjú lọwọ.

Ó sọ̀di mímọ̀ pé, òsìsẹ́ ilésẹ́ ọlọ́pa náà lówà lẹ́nu isẹ́ àkànse láti ìpínlẹ̀ Kogi síì ìpínlẹ̀ Èkó.

Alákoko ilésẹ́ ọlọ́pa nípinlẹ̀ Ògùn, ọ̀gbẹ́ni Edward Ajogun sèpèjúwe ìsẹ̀lẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí èyí tóburújài tíkòsì bófimu àmọ́ sáà, ó ti pasẹ ipararọ láti fọwọ́ òfin mú àwọn tíwọ́n furasí tóòkù.

Idogbe

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *