Yoruba

Ibugbamu Afefe Gaasi Gb’emi Eniyan Marun L’eko

Eeyan marun ni iwadi ti fi idi re mule pe won ti gbemi mi nibi ijamba afefe gaasi to bu gbamu, eyi to waye laaro oni ni Baruwa, agbegbe Alimoso nipinle Eko.

Oko elejo to gbe afefe gaasi naa lo bu gbamu lasiko ti oko elejo naa nja afefe inu re sibudo ti won ti n ta afefe gaasi lagbegbe naa.

Adele oludari ajo to n ri si isele pajawiri, NEMA, Ogbeni Ibrahim Farinloye to topinpin isele na salaye wipe eeyan meta ni won doola emi won pely oku eeyan marun ti won gbe jade nibi isele naa.

O salaye wipe awon meteeta ti won doola won naa ni won tigbe lo sile iwosan fun itoju pajawiri.

Ogbeni Farinloye salaye wi pe ijamba naa lo way nipase ero amunawa ibudo ti won ti n ta afefe gaasi naa leyi ti won tan lasiko ti oko naa n ja afefe gaasi.

Idogbe/Salaudeen

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *