Yoruba

NIMC Kede Aseyori Re Laarin Osu Kan

Ajo to n risi iforukosile fun numba idanimo omo ile yi NIMC ti so wipe oun ti foruko awon to le ni millionu meta sile laarin osun kejila odun 2020 si osu kini odun 2021.

Oga agba ajo NIMC Omowe Aliyu Aziz lo soro yi di mimo ninu iforowero pelu awon oniroyin.

O ni lowolowo bayi, ajo naa ti fun awon omo ile yi to le logoji millionu ni number idanimo omo ile yi won.

Oga Agba ajo NIMC salaye wipe ajo naa bere iforukosile fun nomba idanimo omo ile yi lodun 2012.

Omowe Aziz wa bu enu ate lu bi awon ogooro o mile yi o se lo anfani awon odun to ti koja lati foruko sile.

O fikun wipe ajo naa yio fowosowopo plelu eka aladani ati ti ijoba lati samulo awon ohun ti o wa nikawo won fun adeyori to tubo ya ati jafafa siii.

NET/Dada

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *