Ile igbimo asofin agba keji nile yi ti fowosi liana idasile ile eko ekose oluko ti mo ero toje tijoba apapo nilu Ago iwoye, nipinle Ogun.

Abo igbimo to n risi oro awon ile eko giga, lori idasile ile eko naa silu Ago Iwoye nipinle Ogun atawon nkan min lodi bibuwolu niwaju ile igbimo asofin naa pelu idari Ogbeni Femi Gbajabiamila tiise adari ile.

Eni to sagbateru aba ofin ohun to tun je igbakeji akojanu ile fegbe osele to kere julo, ogbeni Adeseun Adekoya sope aba naa ni yoo fayegba idasile ile eko ijoba apapo akoko sile ijebu lati gba tileyi tigba ominira lodun 1960.

Nigba tohun sapejuwe idasile ile eko naa gege bi aseyori nla, Ogbeni Adeseun safikun oro pe ile eko naa yoo fun awon eeyan lanfani si eto eko to dinwo tosi muna doko fawon omo bibi ati olugbe ile Ijebu.

Ile igbimo asofin agba keji buwolu idasile ile eko ekose oluko ijoba apapo nilu Ago Iwoye.

Blessing Adesanya/Ayodele Olaopa

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *