Yoruba

Àarẹ Buhari késí ilẹ̀ òkèrè láti dọwọ́pọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ Nàijírìa

Àarẹ Muhammadu Buhari ti rọ àwọn olùdóokowò láti orílẹ̀dè Germeny pé kíwọ́n wá gbé ilésẹ́ ajé kalẹ̀ papáà lẹ́ka ohun àmúságbara.

Nígbà tó ńgba ìwé ìwosẹ́ látọ̀dọ̀ asojú ilẹ̀ Germany sórílẹ̀èdè Nàijírìa Birgitt Ory, nílé àarẹ Buhari fọwọ́ ìdánilójú sọ̀yà fáwọn oní ilésẹ́ ajé láti orílẹ̀èdè Germany, pé ìjọba yóò buọlá fún àdéhùn gbogbo.

Ìwé àdéhùn lárin orílẹ̀èdè méjèjì lórí iná ọba yóò mú kí ìbásepọ̀ wọn gbòòrò si.

Nínú ọ̀rọ̀ rl, asojú ile Germany sórílẹ̀dè Nàijírìa, Birgitt Ory sọpé ànfàní ńlá lójẹ́ fún láti sisẹ́ sin ilẹ̀ Nàijírìa, èyí tóun ti fojú sọ́nà fun, lọ́jọ́ pípẹ́.

Tósì sàpèjúwe ilẹ̀ Nàijírìa gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀èdè tótóbi jù tósì se pàtàkì jùlọ nílẹ̀ adúláwọ̀.

Kẹmi Ogunkọla/Oluwakayọde Banjọ

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *